Imo girama ede geesi ni Yoruba: "Alike"

Latari awon asise keekeke ti awon eniyan ma n se nipa sise amulo ede geesi.

A ma gbiyanju lati se awon alaye ati atupale awon koko pataki nibi nipa girama ede geesi.

Lonii, a ma so nipa asilo orisii oro kan ti n je "alike".Opolopo awon eniyan ma n lo orisii oro yii gege bi Adjective, eleyii ti n sise eyan ninu gbolohun. Sugbon oro aponle ti a mo si Adverb ni.

E yii tunmo si wi pe, gbogbo igba to ba jeyo ninu gbolohun, o gbodo maa sise pelu oro ise ti a mo si verb.

E je ka ye gbolohun yii wo:

"My girlfriend and I have an alike hairstyle."

Ninu gbolohun oke yii, won lo "alike" lati sise eyan fun "hairstyle" to je oro oruko (Noun).

Eleyii si mu girama inu gboluhun yii fori gbagi bi moto ti bireeki re faali.

"Alike" ki i se adjective, adverb ni.

Bo se ye ki gbolohun naa lo ni yii:

My girlfriend and I have the same hairstyle.

My girlfriend and I have a similar hairstyle.

Sugbon sa, ti a ba fe lo "alike"ninu gbolohun naa. A ni lati se atunto tabi atunko awon oro inu gbolohun naa.

Apere: Our hairstyles are alike.

Girama inu gbolohun yii pegede nitori "alike" duro gege bi oro aponle fun oro ise inu gbolohun naa to je "are".


Ma duro nibi, sugbon inu mi yoo dun lati ri afikun ti yin ati apere orisiirisii nipa ona ti a le gba lo"alike" lona to pegede ninu gbolohun ede geesi.
Share on Google Plus

About Olayemi Olatilewa

www.olayemioniroyin.com

Whatsapp +2348032394964

0 comments:

Post a Comment