Iba oga oniroyin: Chris Kehinde Nwandu @ 50

Chris Kehinde Nwandu
O wu gbogbo eye ki won lola bi eye okin, aso aran ni won o ni nile.

O wu eye aparo ko ba lekeleke dogba, ailaso funfun nile ni o je keye aparo o niyi.

Gbogbo eni korin ko ni i korin gidi.

Aimoye sigidi to lenu ti o le soro.

Gbogbo akewi ko lo jina denu.
To ba jo bi iro, Olatunbosun ni ke e bi.
Olatunbosun Oladapo ti fogbon nla rayi lowo mi.

Gbogbo omi dudu ko laro to se reso.
Gbogbo eni sise opolo ko nise won fakiki.
Gbogbo oniroyin ko lo mo ojuleja ise aroye to mogbon dani.

Iba Chris Kehinde Nwandu

Ogbontarigi akoroyin ti n ta koko omi seti aso.
Alujannu oniroyin ti n kun yunmuyunmu laajin.

Aribisala, okunrin ogun, takuntakun loju ogun, erujeje ti won bo bi oke.

Oniroyin kan ju oniroyin kan lo.

Iba Chris Kehinde Nwandu

CKN ma gbo, bo ba lo igba odun laye, odun kan pere ni won o fi ka fun o lode orun.

Irawo re ko ni wookun laelae to ba wola Eledumare oba oke.

Iwaju lojugun n gbe, iwaju lo ma lo.
Asodunmodun lawo asodunmodun, asoromoro lawo asoromoro.

Bo se n sodun loni, o tun seemi ninu ola ati alaafia. Ase

#HBD CKN@50
Share on Google Plus

About Olayemi Olatilewa

www.olayemioniroyin.com

Whatsapp +2348032394964

0 comments:

Post a Comment