Ilẹkun ile isẹ iroyin ti ja sọnu (2)Bi eniyan ba n wa ojulowo iroyin ti ko labula, ẹ ma je n tan yin, awon iroyin bẹẹ ko si lori telifisan tabi rẹdio mọ. Bẹẹ si ni ẹ ko le ri i loju iwe iroyin ojoojumọ. 

Ori ayelujara lo wa. Bi eniyan ba n fẹ iroyin oju ẹsẹ, awon iroyin yii ko si lori ibi kankan mo yato si ori ayelujara.

Otitọ ọrọ bi isokuso ni i ri.


Pupọ awon iroyin ori redio, telifisan ati iwe iroyin lo je awon iroyin ti won ti jọ bi elubọ. Pupo awon nnkan to se ara loore ni won yoo ti jọ danu latari ibẹru ati awon ofin kan-anpa ti ajọ ti ijoba gbekalẹ ti n se alaboju won se fun awon ile ise iroyin. 

Se won ni ko si bi irunmu alagbaro se gun to, ẹni gbe ise fun lọga rẹ. Sẹ ẹ mọ wi pe awon ijoba ni won fun won ni iwe asẹ lati sise.
Awon nnkan won yii si mu ki adinku agbara de ba awon ile ise iroyin eleyii ti awon eniyan ti gbara le gege bi orisun lati mo ohun to n sẹlẹ lawujọ.

Ohun to tun bọ ja irawo won ko ju olaju ati ero igbalode to wole de lọ.

Mi o so wi pe ojulowo ile ise iroyin ko si, sugbon pupo won ni won ko le se bi won se fẹ.
Pelu ipo ti awon ile ise iroyin wa, njẹ awa le gba wi pe eni sise nibe nikan loniroyin gidi? Iro nla to jina si otito ni. 

Bi o tilẹ je wi pe aimoye sawo-sogberi naa ni won wa kaakiri, sibesisbe, ise iroyin sise lai si ibẹru tabi ase abẹnilori maa niyi loju awon eniyan awujo.

Omoyele Sowore ti n sisẹ iroyin rẹ bọ ọjọ ti pẹ. Orisii agbekalẹ isẹ iroyin rẹ lo je wi pe yoo soro fun ile ise iroyin kankan lati gba wole lai se wi pe won bu omi laa nipa agbekala awon ofin won. 

Pupo ninu awon ilana yii lo si je ohun ti ko le ba Sowore lara mu. Sugbon nipa agbara imo ero eleyii ti olaju gbe wole.  

Omoyele Sowore dagbo gbe bẹẹ lo si daraba nla ti won bo loni bi oosa akunlebo. Omoyele Sowore yii ni alase Sahara Repoters.

Mo si n tesiwaju... 
Share on Google Plus

About Olayemi Olatilewa

www.olayemioniroyin.com

Whatsapp +2348032394964

0 comments:

Post a Comment