Itan igbesi aye Ligali Mukaiba olorin apala ilu Epe 2

Image result for ligali mukaiba 


Agba Olorin wo ni mo fe so nipa re lonii?

Se e ranti wi pe odun 1933 ni won bi Ayinla Omowura. Agba olorin ti mo fe so lonii, odun 1924 lo wa saye?

Ojo kerin osu karun-un odun 1924 in won bi Ligali Mukaiba to je olorin apala ni agbegbe Ajangbadi to wa niluu Epe. Oba Eshugbayi Eleko lo wa lori oye gege bi oba Eko ni akoko naa.

Oruko baba re ni Ismaila Sanni Mukaiba nigba ti oruko iya re si je Sariu Mukaiba.

Ise apeja n baba Ligali n se, ise yii naa si ni omo re gbonju ba lowo re. Ligali a ma ba baba re lo sodo eja, ti oun naa si n peja wale.

Sebi Yoruba lonii ati kekere ni musulumi ti n ko omo re laso, eyi gan an lo mu ogbeni Sanni Ismaila fi oju omo re mo ise ti n se lati pinisin.

Sugbon nigba to ya Ligali Alade Adebayo Mukaiba ti opolopo mo si Ligali Mukaiba ni oun fe lo ko se sabere dowo di tailor.

Ligali sie tailor fun awon odun bi meloo kan. Igba to sise tailor ti ko ri ona abayo lo ba ya sidi ise orin. Eleyii to ti wa lokan re fun igba pipe.

Bi ere bi awada Ligali ti bere si korin aladidun faye gbo. Orin kiko je e lowo, nigba to di odun 1945, ni akoko to pe mo odun mokanlelogun, Ligali Mukaiba so orin kiko dowo bee lo so ilu apala dowo ti pate re lodo ariya.

Siwaju sii, ko si akosile kankan eleyii to so wi pe Ligali kose orin leyin olorin kankan saaju ko to gbe igba orin kiko. Ko tele olorin kankan rin ninu itan igbe aye re ko to da ti e sile gege bi a se ri Ayinla Omowura se sise leyin Osho Oba ti Sir Shina Peters si fi igba kan wa leyin Obey Commander.

Gege bi iwadii se fi ye wa, awon kan so wi pe, laaarin odun 1945 si 1980 ni irawo orin Ligali Mukaiba fi le roro loju orun. Ko wa sibi to ti pate ere re ni lu Epe taye ki i pe woran re. Sugbon sa, oun nikan ko lo n role ni akoko naa ni ilu Epe.

A ni awon olorin bi Alhaji Alabi Elewuro ati Salau Onisakara ti awon naa je olorin nigba naa. Sugbon ikolu tabi itakangbon maa saba waye laarin Ligali Mukaiba ati Alabi Elewuro ti won jo n korin niluu Epe.

Itakangbo laarn Alabi Elewuro ati Ligali po to bee gee to je wi pe, awon ololufe won naa a forin won ta kangbon laarin ara awon.

Eleyii si fa iyapa laarin awon ololufe orin won ni ilu epe. Awon apakan ti won pe ara won ni Ijebu Epe ni leyin Ligali ko solorin mo. Nigba ti awon Epe Eko ni Alabi Elewuro lagba olorin.

Lara awon ololufe Ligali Mukaiba ti won da egbe ololufe orin Ligali Mukaiba sile ni Borokini onifaaji ni, oloye Abu Olododo. Oloye Abu Olododo je omo Kwara, o si sapa re nipa gbigbe orin Ligali laruge laarin awon omo Afonja bakan naa lo tun se fun un ni agbegbe Ijebu.

Igbe aye to tobi ni Ligali Mukaiba gbe gege bi agba olorin aye atijo. Gbogbo itu meje ti ode n pa nigbo ni oun naa pa lagbo olorin. Awon awo orin re lo bi ogorun, aya merin ni Ligali fe nigba ti awon omo re n lo bi mejilelogun.

Koda, awon merin ninu awon omo re ni won yan ise orin kiko gege bi ogun ti won jogun lowo baba won.

Ojo kejilelogun osu kefa odun 1984 tun je ojo kan ti a ko le gbegbe nipa itan igbe aye Ligali Mukaiba. Nnkan bi ogota odun ni Ligali lo laye ko to sile bora bi aso sugbon awon awo bi ogorun si wa laaye titi do ni.

Share on Google Plus

About Olayemi Olatilewa

www.olayemioniroyin.com

Whatsapp +2348032394964

0 comments:

Post a Comment