Ambode gbegbe akoni obirin ti Ebola seku pa nipinle Eko

 
Awon Yoruba bo, won ni ore pe, asiwere eniyan gbagbe. Yoruba kan naa lo tun so wi pe, baa ba seni loore ope laadu. Eni a si se loore bi ko ba dupe, bi igba ti olosa koni leru lo ni. 

Okunrin  kan ti oruko re n je Deji Ayowole lo koro oju bi ijoba ipinle Eko se gbagbe lati bu ola fun Dokita  Stella Adadevoh to padanu emi re latari ajakale arun ebola to ya wo Naijiria nigba kan se yin.

Dokita yii lagbo wi pe, o koko kofiri arun naa lara alaisan ti won gbe wa si osibitu re. Lara ilakaka re lati ma je ki alaisan naa sawo igboro ti arun naa yoo fi tan kale ti ko wa ni lojutu lo mu oun naa ko arun naa eleyii to pada mu lo sorun aremabo.

Ni akoko ayeye aadota odun ti won ti da ipinle Eko sile, o joniloju wi pe ipinle Eko ko ranti obirin akoni naa mo. Eleyii lo mu Ogbeni Deji Ayowole se abamoda aworan re soju titi eleyii ti won gbelero lori ayarabisa.

Sugbon se a wa le da ijoba ipinle Eko lebi ni? Ohun to wa niwaju ijoba po gan-an. A ti wi pe, ti a ba n so wi pe ijoba, sebi awa naa ni ijoba. Owo gbogbo wa si ni asise naa wa. Owo wa naa si tun ni atunse ti wa eleyii ti Ogbeni Deji se.
Share on Google Plus

About Olayemi Olatilewa

www.olayemioniroyin.com

Whatsapp +2348032394964

0 comments:

Post a Comment