Asa dida ti wa tipe ninu orin ile Yoruba

Image result for instagram adegoroye ayinde 
Aimoye eroja lo kun inu orin kiko ko to di ohun taye gbo bi orin alarinrin. Iya elewe omo le saye wi pe, tewe agbo ko ba pe a maa mu adiku ba ise iwosan.

Nipa akiyesi, lara awon ohun to maa n jeyo ninu orin ni asa dida. Eleyii le ma wopo pelu gbogbo olorin, subon awon kan gba asa dida ninu orin gege bi sitayi orin ti won.

Eleyii to je wi pe, eroja orin won ko ti i pe lai dasa tuntun fun awon olugbo won.

Nje kini won pe ni asa dida? Asa dida je oro tabi gbolohun eleyii ti aponle re ko kun to lati wa ninu ede oro enu. Eleyii lo fi je wi pe kii se gbogbo ipejo awon eniyan ni a ti le dasa.

Bakan naa lo si ni irufe isowo awon eniyan awujo ti asa naa wopo si lenu. Awon kan tun gba wi pe, awon ti won ba je asa tabi ti oju won ba re, kii soro meji ki won to dasa. Asa dida a maa wopo ninu oro enu won.

Bakan naa ni awon odo ri asa dida gege bi eni to mo ohun ti n lo lowo nigboro. Nipa sise afihan wi pe awon mo ohun ti n lo lowo, won maa dasa tuntun to wa lode ninu gbogbo itakuroso won. 

Orisiirisii ona ni asa ti awon olorin lo ninu orin won ma gba waye. Bakan naa ni gbogbo won lo ni ise ti won se. Asa ti olorin lo ninu orin re le je eyi ti awujo se eda re.

Eyi tun mo si wi pe, asa kan le maa lo nigboro ki olorin si mulo ninu orin re ati je ki awon eniyan mo nipa asa dida tuntun to gbode.

Nipa awon asa dida, ti olorin mu lawojo wo inu orin re le wa latari orisiirisii isele ti n sele lawujo.

Bakan naa awon olorin a tun maa seda asa tuntun fun awon ololufe won, lopo ara won. Asa dida tuntun lati owo olorin le je itewogba tabi idakeji re. Eleyii nii se pelu bi olorin tabi bi orin naa se lokiki tabi gbayi lawujo.

Kowa si asa dida kankan to waye ti kii lo, yala eleyii to gbayii loju araye tabi eyi ti won koyin si.

Igba kan lo, igba kan bo ni. Lati aye awon Ayinla Omowura, Haruna Ishola ni won ti dasa bi "O si o da nile pako, Soyoyo ati bee bee lo.

Laye ode oni, pupo ninu awon omo onifuji ni won feran asa dida ninu awon orin won. Lara awon asa ti won ti da seyin ni:

O saamo
Para lo
Jeun soke
Ma lo bi skoda
Oga ade
Won a tun maa dasa bi, tan ba ni so ti de, won ni so fe de pa ni?

Laye ode oni, a tun ri awon asa dida bi
Gbera
Tuale
No more tuale
Buate
E le da je
Gbenu si
Kan senu no bi karrot
Fo won lenu
Sempe.

Awon omo onifuji nikan ko ni won dasa  ninu awon orin won. Laye ode oni, a tun ri awon kan ninu ere fiimu agbelewo ti won feran lati ma pase asa dida tuntun fun awon ololufe won. Bakan naa ewewe, awon olorin pakaleke takasufe naa o gbeyin nipa sise amulo asa dida ninu orin won. Ninu awon orin won ni a si ti ri awon asa bi

No lele
Eni duro
Nothing dey happen
No long thin
File
ooshe
jooo o atbb

Pupo ninu awon asa dida yii a maa fun ni koriya nigba ti awon kan duro gege bi awada, eebu nigba ti awon kan ko ni itunmo kankan tayo wi pe won kan dun lenu ni pipe lasan lo.

Awon asa dida kan wa ti opo eniyan gba gege bi oro alufansa, oro idoti tabi oro odi eleyii ti won ni ko bojumo lawujo wa. Die ninu awon asa naa ni lalakibo, run down, foka sibe, olosho ati bee lo.


Ohun ti odajo ni wi pe a ko le fi asa dida se odiwon orin gidi. Asa dida ninu orin se apejuwe ero olorin ati iru awon ti olugbo re je.

Iru asa dida wo leyin feran tabi ti e korira. E fi sowo siwa nigba ti a setimamokan, sempe, taa wararo, lati gba awon esi yin lori ero ayelujara wa.

Share on Google Plus

About Olayemi Olatilewa

www.olayemioniroyin.com

Whatsapp +2348032394964

0 comments:

Post a Comment