Itan igbesi aye Ayinla Omowura

Image result for ayinla omowura
Ayinla Omowura

Enikeni ko le so pato ojo to daye, nitori ko si akosile kankan ti a ri dimu nipa ojo ibi re. Sugbon ohun to daju ni wi pe, odun 1933 ni won bi Alhaji Waidi Anigilaje Ayinla Omowura, eni ti pupo ninu awon ololufe re mo si Eegunmogaji.

Kosi ba se fe si iwe itan awon olorin ni ile Afirika, Naijiria, ile Yorubaawa, lai menu ba ogbontarigi onkorin Apala to dagbere faye lọjọ kefa osu  karun-un odun 1980 nipinle Ogun.

Fun igba pipe ni Ayinla Omowura fi tele Osho Oba, eni to je   olorin nigba aye re saaju ki Ramoni Adewole to je onilu to fa Ayinla Omowura mora lati da egbe orin tuntun sile.
  
Adewole, ti gbogbo eniyan mo si Onilu Ola pada je okan pataki lara awon onilu leyin Ayinla Omowura ni agba aye re.

Okiki Ayinla Omowura gbinaya ni akoko to dara po mi ile ise orin Emi Nigeria lodun 1970. Lara awon orin olokiki re to se nigba naa ni "E MA FOWO SOYA SI WA MO" DANFO O SIERE, " E MA TORI OWO PANIYAN" AJANNU ELERE ati bee bee lo.

Kaakiri tibutoro ile Naijiria ni won ti tewo gba orin Ayinla Eegunmogaji. Bakan naa ni awon ilu bi Lome, Abidjan, Cotonue, ilu awon Aganyi, ile Saro pata ni won ti n pe b apala orin Baba Akeem bi igba ti won pebo odun Osun Osogbo.

Gege bi akosile ile ise orin ti n gbe Ayinla Omowura jade se so, o kere tan, nnkan bi egberun lona aadota (50, 000) awo orin Ayinla ni aye dura lojo ti awo orin naa ba koko de ori igba fun tita.

Eleyii to sajoji lagbo amuludun ni asiko naa, ko de fe e si olorin to le aseyori yii ba ni awon akoko teegun Ayinla jo lode orin kiko.

Ni ibudoko awon oloko, ile oti, agbo ariya, adugbo sadugbo ni awon eniyan ti feti ko orin Ayinla Omowura ni akoko to ba ju awo tuntun sile bi eni wi pe ko solorin mii mo lode laye.

Ni nnkan bi odun mewaa ti Omowura lo pelu Emi Nigeria, awo bi ogún (20) lo po sile eleyii ti gbogbo re si n gbona tinu teyin bi ajere.

Odun 1975 ni Ayinla re Mecaa to si pada bo wa sile, igba o de ni gbogbo aye pe ni Alhaji tuntun. Anigilaje pada de sinu ile ola, pijo lo gbe pamo sagbala, mesi oloye Layinla OmoWura fi n jaye kiri l’Egbe Alake.
  
Ti a ba n so nipa ojulowo ogbon orin, agbekale orin to moyanlori, alaye baba oro to fogba yanga, edoki ede ti n kani laya, ohun orin to dun morainrain leti, awon onwoye ni Ayinla Omowura ni ka gbe fun nitori akande eniyan kan ni.

Ni odun 1977, ogbeni Benson Idonije to je oniroyin amuludun wa ni yara agbara pelu Anigilaje ni akoko ti gbe orin re kan na pelu awon elegbe re. Ohun ti oniroyin naa so ni yii.

"Mo ri ojulowo talenti to se mi ni kayeefi. Mo si ri isafihan isipaya orin to koja oye mi. Ayinla o gbe iwe dani, ori lo ti n mu gbogbo ohun ti ko jade. Bo se n pari okan lo tun fo mo mii lai fi okan pe meji bee ni gbogbo orin re lo jinle kọja ohun ti eniyan le fo alaye re mọle lọjọ kan soso."

Benson Idonije lo se alaye yii lojo to foju kan Ayinla Omowura nile orin.Orisii alaye ati awon nnkan ti n sele lawujo wa lara awon ohun ti Ayinla Omowura maa n menu ba, yala lati fi pe akiyesi awon eniyan si ohun ti n lo lowo tabi naka abuku si iwa ibaje.

Lara iru awon orin naa ni Danfo O Siere nibi ti Ayinla ti n se afomo fun oko akero voxsiwagen ti won ni oko naa fa ijamba loju popo.

Eegunmogaji ko sai tun korin bi Naijiria se dawo oko wiwa won kuro lowo osi pada sowo otun lodun 1972.
Owo udoji nko? Owo udoji ti won san fawon osise tun wa lara ohun ti Ayinla de mole ninu orin re ko le duro gege bi itan akosile ti ko ni pare laelae.

Yato isele awujo, baba Adija Kubura a tun maa korin ki awon eniyan pataki ti won koja sorun. Eleyii lo se fun Ayinde Bakare ati ologun Muritala Muhammed ti won seku pa lodun 1976.

Ayinla Omowura kii ye ma soro nipa ile olorogun ninu orin re, bakan naa lo si maa n koro oju si awon obirin ti won bora ati iwa ole jija lawujo.

Ayinla Omowura je enikan to nife si ere boolu alafesegba. Eleyii si jewo ninu orin re pelu bo se forin royin asekagba ifesewonse Challenge Cup to waye laaarin Bende Insurance tiluu Benin ati Mighty Jet tiluu Jos to waye lodun 1972.
Ninu ifesewonse odun 1972 yii ni Bende Insurance ti gba ife eye nigba ti won na Mighty Jet pelu ayo meta si meji.
Bakan naa ni alaye asekagba ifesewonse todun 1974 to waye laaarin Mighty Jet ati Enugu Rangers tun jeyo ninu awo orin Anigilaje Ayinla omo won n’Itoko.

Bi eniyan ko tile wo ifesewonse naa sugbon to gbo alaye orin Ayinla, iriri eni naa ko le yato sawon to wa ni papa isere ibi  ti idije naa ti waye pelu bi Enugun Rangers se bo Mighty Jet mole pelu ayo meji sodo


Siwaju sii, lara awon nnkan to tun maa n jeyo ninu orin Ayinla Omowura ni awada, aditu oro, asorege, iforodara, ofo ati ayajo.

Lara awon awo orin ti Ayinla Omowura gbe jade ni Abode Mecca, Late General Muritala Muhamed, Owo Tuntun eleyii ti  won  jade lodun 1977. A D’ARIYO jade lodun 1979. Awo orin ‘A KII SE OLODI WON si je eleyii ti won gbe jade lodun 1980. Lara awon awo orin Baba Halimotu ni “EYIN OLOSELU WA, EMOKAN,E BI KI PAGUN DOJO ALE,

Ogun Ajobo vol 1& 2 1971
Challenge Cup 1972
National census 1973
IRE WOLE DE  1974
Lara awon orin re ni a tun ti ri: Orin Faaji, 25*40 abbl.

Ayinla Omowura ko so wi pe oun korin mo, Alhaji costly co si so wi pe oun jeun  mo, awon aye ni won yo owo re kuro ninu awo tangaran.

Okan ninu awon omo egbe re kan ti je Bayewu to tun je manija re ni wo jo ni  ede aiyede eleyii ti Ayinla si ni ko maa lo. Gege bi a se gbo, Bayewu lo pelu Masiini alukuku ti ayinla ra fun eleyii to ni ko da pada sugbon ti omokunrin naa ko lati dapada.

Nibi ti Bayewu ti n moti lọjọ kefa osu  karun-un odun 1980 ni Ayinla lo ka mo, to si wo  wi pe ko ba oun mu kokoro alukuku naa ti oun ra fun. Bayewu ni ko jo l’Ake ko jo loko ni gbo re ba di fopomoyo nile oti

Ile oti daru gidigidi, Ayinla ko ifoti bo Bayewu, Bayewu ba nawo gbe koopu onigo ti won fi muti lori tabili, lo ba fo igo naa mo Ayinla Omowura lori. Bi eje se n da lori Ayinla ni yii,  oga akorin si se bee fi aye sile nipa pipadanu opolopo eje ko to ri itoju.

Opo awon ololufe re ni ko gbagbo nikete ti won kede iku Ayinla. Aimoye awon eniyan lo si n se ni kayeefi wi pe President olorin apala ti gbe orin re wonu koto. Ki Ayinla Omowura to lo, ninu orin, o se alaye iru iwa to wa lowo iku. E gbo bo ti wi:
Iku oponu olodi abara dudu hohoho
Koni wa kan lara ju ko ma ji won logo kiri
Gbogbo oju pon koko gbogbo ara re ni deru baniyan”
Otiti loro awon agba to ni iku o pa eni an pe, bee ni iku o pa eni ti n pe. Aimoye omo lo fi saye, bee ni Ayinla fi awon iyawo sile saye lo.
Bi Ayinla Omowura ko tile si laye mo.
Bi onirefin ko tile fingba mo, eleyii to ti fin sile ko le parun.
Ti aye ni orin Ayinla Omowura n ta lori igba. Titi aye si awon ololufe n je igbadun re lakotun.

Gbogbo ero to ba n lo s’Egba alake, e ba wa ki won nipinle Ogun.
Bi e ba de Itoko e ki won ke to salaye oro gidi.


Titi doni laye n sedaro Anigilaje, agba on korin to fi geesi korin apala ko to jade laye. Waidi Anigilaje Ayinla Omowura sun re o

 
Share on Google Plus

About Olayemi Olatilewa

www.olayemioniroyin.com

Whatsapp +2348032394964

0 comments:

Post a Comment