Nje e mo nipa ijamba to le sele nipa iwa ibaje oju popo?

Image result for traffic in lagos 
Duro na ga dirẹba, Ani ẹyin ni mo n ba wi sẹ, hẹn, ẹyin naa ni, awako oju ona ti rufin ijọba. Jọọ sare damilohun ibeere mi ni kiamọsa pẹlu suuru. Oga dẹrẹba awako oju-popo, se kosi tẹ ẹ koyin sibi taye kojusi? Kilode to fi je wi pe, oju ona ti awon oko gba bọ gan-an lẹyin mori le tẹ fẹ gba lọ? Ẹ salaye ki gbogbo aye o gbọ. Ohun tẹ ri lọbe te fi waru sọwọ gan-an.  


Ọna ti gbogbo ọkọ n gba b nikan, to jẹ ọna kankan soso, ona yii kan naa le yin mori le tẹẹ fẹ gba lọ. Oju ona yii, ona kan soso ni, awon ọkọ ti n pada bọ nikan nijọba se e fun, Ọna yii ki i se fun awon oko to fẹ jade lọ- pipada bọ lasan ni, ki i se fun lilọ

Ti ẹ ko ba ri akole ijoba ti n sapejuwe orisii ona to jẹ, sebi ẹ loju, ẹ si ri wi pe awon ọkọ ti n pada bọ ni kan ni won tobọ loju ona yii. Ọkọ meloo lẹyin ri leyin yin to fẹ gba ibi eyin gba? 

Dẹrẹba alagidi, oya pada seyin kiaia ki okete to boru mọọ lọwọ.
Ojo ti sigidi ba fẹ sere ẹtẹ lo n renu omi lo re e wẹ. Oori ko ni foju koorun ko ma yọ gẹẹrẹgẹ. Eniyan ko ni tẹlẹ jaujau ni Koso ko ma rija Sango ọko oya. Eni ba ti rufin ijoba ilẹ yii dandan ni ki abẹ bẹ ẹ lọwọ pẹrẹgẹdẹ.

Oju ona ti ijoba se fun oko lati gbalọ soke yato si eyi ti won se lati gba pada wa sile. Eyi ti won se fun bibọ ọkọ kii se fun gbigbalọ. Alagemo ti bimo rẹ tan, aimojo ku sọwọ gbogbo wa. E ma je a balu je nipa titapa sofin ti ijoba ile yii lakale loju popo.
Ijoba ti seto fun wa lati wa lalafia, e ma je fowo ara wa fajamba eleyii to le se akoba fun gbogbo arina oju-popo.

Nibi ẹ ti n gbe ọkọ bọ loju ona ti ijọba se fun gbigba lọ nikan. Eni to fẹ fo oju titi, oke lasan ni i wo, ẹniẹlẹni o wosalẹ. Nigba to jẹ wi pe ọkọ kankan ki i wa lati isalẹ.  Sugbon dirẹba arufin ti gbọkọ gba oneway, ni wahala ba sẹlẹ o. O se bẹẹ gba ẹniẹlẹni to fe soda danu. Yeepa! Ikunlẹ abiamọ o. Eni ti o rokan osibitu dero ile iwosan osan gangan.

Oko ti n bọ loke gan ko mo wi pe dereba arufin ti gba oneway bọ latisale. Onimoto ti n bo loke jade ni kona lo ba di kosa pelu deregba arufin ti n bo latisale. Gbogbo re ba disu ata yan-anyan
E yee gba oneway mo iwabaje ni, e je a tele gbogbo ofin irinna oju popo ka ma ba fi tiwa sejamba fara ilu.
Eyin naa e wo sunkere gbakere oko bo se gun bi afara odo oya, latari direba kankan soso to tapa sofin ijoba. E yee wu iwa ibaje mo ohun ti ko daa ko loruko meji. Ko daa ni i je. 

Sebi awon Yoruba ni won onilu ki i fẹ ko tu. Ilu ti wa ni yii, ojuse ti wa ni lati tunse nipa ti tẹle awon ofin oju popona. Awon iwa ta le wu ta ba de awon ilu okeere, o se je iru iwabaje bayii lawa tẹpẹlẹ mo? Ikanju ohun suuru, ọgbọgba ma ni. 

Asare tete kan ko ni koja ile, Eniyan to si se suuru duro loju ona to ye ko gba ko ni sun soju ona. Ta ba n wuwa ibaje loju popona, e je kan maa ranti ohun to le teyin re yo. Ta a ba rufin irina oko, o le ba dukia je, o le fa ipalara fun wa, o si le mu emi eniyan lo pelu. E je ka se pele, alagemo to se jeje iku n pa won, anbosibosi opolo ti n jan ara re mo le. Suuru lo nile aye, e je ka mu suuru ta ba rina, nitori onisuuru ni jogun aye.
 
Share on Google Plus

About Olayemi Olatilewa

www.olayemioniroyin.com

Whatsapp +2348032394964

0 comments:

Post a Comment